14. Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u Rẹ̀;ó sọ májẹ̀mú Rẹ̀ di mímọ̀ fún wọn.
15. Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa,nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.
16. Yípadà sími, kí o sì ṣe oore fún mi;nítorí pé mo nìkàn wà, mo sì di olùpọ́njú.
17. Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi;kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú ù mi.
18. Kíyèsí ìjìyà àti wàhálà mi,kí o sì darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn.
19. Kíyẹ̀sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi,tí wọn kórìírá a mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.
20. Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú,nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.
21. Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́;nítorí pé mo dúró tì ọ́.
22. Ra Ísírẹ́lì padà, Ìwọ Ọlọ́run,nínú gbogbo ìṣòro Rẹ̀!