Sáàmù 24:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún Rẹ̀,ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú Rẹ̀;

2. Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ Rẹ̀ lélẹ̀ lórí òkunó sì gbée kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

3. Ta ni yóò gun òrí òkè Olúwa lọ?Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ Rẹ̀?

4. Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,ẹni tí kò gbé ọkàn Rẹ̀ sókè sí asántí kò sì búra èké.

Sáàmù 24