Sáàmù 21:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Áà! Olúwa, Ọba yóò yọ̀ nínú agbára Rẹ,àti ní ìgbàlà Rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!

2. Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn Rẹ̀ fún un,bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu Rẹ̀. Sela

3. Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nàìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.

4. O ní ọwọ́ Rẹ, ìwọ sì fi fún un,àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.

5. Ògo Rẹ̀ pọ̀ nípaṣẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún-un;ìwọ́ sì jẹ́ kí iyì ọlánlá Rẹ̀ wà lára Rẹ.

Sáàmù 21