Sáàmù 2:7-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;lónìí, èmi ti di baba Rẹ.

8. Béèrè lọ́wọ́ mi,Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀ èdè di ìní Rẹ,òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún Rẹ.

9. Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọnìwọ yóò sì rún wọn wómú wómú bí ìkòkò amọ̀”.

10. Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n;ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.

11. Ẹ ṣin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rùẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.

12. Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínúkí ó má ba à payin run ní ọ̀nà yin,nítorí ìbínú Rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi i ṣe ibi ìsádi wọn.

Sáàmù 2