Sáàmù 136:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Fún ẹni tí ó kọ lu àwọn ọba ńlá;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

18. Ó sì pa àwọn ọba olókìkínítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

19. Síónì, ọba àwọn ará Ámórìnítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

20. Àti Ógù, ọba Báṣánì;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

21. Ó sì fi ilẹ̀ wọn fúnni ní ìní,nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

22. Ìní fún Ísírẹ́lì, ìránṣẹ́ Rẹ̀,nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

23. Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

Sáàmù 136