Sáàmù 125:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Bí òkè ńlá ti yí Jérúsálẹ́mù ká,bẹ́ẹ̀ ní Olúwa yí ènìyàn káláti ìsinsìnyí lọ àti títí láéláé.

3. Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburúkì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;kí àwọn olódodo kí o máa bafi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.

4. Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.

5. Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn; Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Ísírẹ́lì.

Sáàmù 125