Sáàmù 122:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Jérúsálẹ́mù, ìwọ tí a kọ́ bí ìlútí o fi ara mọ́ra pọ̀ ṣọ̀kan

4. Níbi tí àwọn ẹ̀yà máa ń gòkè lọ,àwọn ẹ̀yà Olúwa,ẹ̀rí fún Ísírẹ́lì, látimáa dúpẹ́ fún orúkọ Olúwa.

5. Nítorí ibẹ̀ ni a gbé ìtẹ́ ìdájọ́ kalẹ̀,àwọn ìtẹ́ ilé Dáfídì.

6. Gbàdúrà fún àlàáfíà Jérúsálẹ́mù;àwọn tí o fẹ́ ọ yóò ṣe rere.

7. Kí àlàáfíà kí ó wà nínú odi Rẹ̀,àti ire nínú ààfin Rẹ̀.

8. Nítorí àwọn ọkùnrin àti àwọn ẹgbẹ́ mièmi yóò wí nísinsìyí pé,kí àlàáfíà kí ó wà nínú Rẹ̀;

9. Nítorí ilé Olúwa Ọlọ́run wa,èmi yóò máa wá ire Rẹ̀.

Sáàmù 122