53. Ìbínú dìmí mú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburútí wọ́n ti kọ òfin Rẹ sílẹ̀.
54. Òfin Rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin miníbikíbi tí èmi ń gbé.
55. Ní òru èmi rántí orúkọ Rẹ, Olúwa,èmi yóò sì pa òfin Rẹ mọ́
56. nitori ti mogba ẹ̀kọ́ Rẹ gbọ́.
57. Ìwọ ni ìpín mi, Olúwa:èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ Rẹ.
58. Èmi ti wá ojú Rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi:fún mi ní oore ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu Rẹ.
59. Èmi ti kíyèsí ọ̀nà mièmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin Rẹ.
60. Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́raláti gbọ́ràn sí àṣẹ Rẹ.
61. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn,èmi kò ní gbàgbé òfin Rẹ.