113. Èmi kóríra àwọn ọlọ́kàn méjì,ṣùgbọ́n èmi fẹ́ òfin Rẹ.
114. Ìwọ ni ààbò mi àti aṣà mi;èmi ti mú ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ Rẹ.
115. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin olùṣe búburú,kí èmi lè pa àṣẹ Ọlọ́run mi mọ́!
116. Gbé mi sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Rẹ,kí èmi kí ó lè yèMá sì jẹ́ kí ojú ìrètí mi kí ó tì mí.
117. Gbé mi sókè, èmí yóò sì wa láìléwu;nígbà gbogbo ni èmi yóò máa júbà òfin Rẹ.
118. Ìwọ kọ gbogbo àwọn tí ó sìnà kúrò nínú òfin Rẹ,nítorí ẹ̀tàn wọn asán ni.
119. Gbogbo àwọn ẹni búburú ní ayé ni ìwọyọ kúrò bí i ìdàrọ́;nítorí náà, èmi fẹ́ òfin ẹ̀.
120. Ara mi wárìrì ní ìbẹ̀rù nítorí Rẹ̀:èmi dúró ní ìbẹ̀rù òfin Rẹ