Sáàmù 118:26-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ìbùkún ni fún àwọn tí ó wá ní orúkọ Olúwa.Láti ilé Olúwa wá ní àwa fi ìbùkún fún ọ.

27. Olúwa ni Ọlọ́run,ó ti mú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ tàn sí wa lárapẹ̀lú ẹká igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ

28. Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ;ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga

29. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;nítorí tí àánú Rẹ̀ dúró láéláé.

Sáàmù 118