Sáàmù 116:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.

2. Nítorí ó yí etí Rẹ̀ padà sí mi,èmi yóò máa, pè é ní wọ̀n ìgbà tí mo wà láàyé.

3. Òkun ikú yí mi ka,ìrora isà òkú wá sórí mi;ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.

4. Nígbà náà ni mo ké pé orúkọ Olúwa:“Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi”

5. Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́ ó sì ní òdodo;Ọlọ́run wa kún fún àánú.

6. Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.

7. Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi Rẹ,nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.

Sáàmù 116