Sáàmù 107:33-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Ó sọ odò di ihà,àti orisun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.

34. Ilẹ̀ eleso di aṣálẹ̀ nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú Rẹ̀;

35. O sọ ihà di adágún omi àtiilẹ̀ gbígbẹ di oríṣun omi

36. Níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,wọ́n sì pìlẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé

37. Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàràtí yóò ma so èso tí ó dára;

38. Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iyekò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dín kù.

39. Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú,ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù

Sáàmù 107