8. Ó rántí májẹ̀mú Rẹ̀ láéláé,ọ̀rọ̀ tí ó páláṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran;
9. Májẹ̀mu tí ó ṣe pẹ̀lú Ábúráhámù,àti ìbúra tí ó búra fún Ísáákì.
10. Ó fi da Jákọ́bù lójú gẹ́gẹ́ bí àṣẹsí Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé
11. “Fún ìwọ ní èmi ó fún ní ilẹ̀ Kénánìgẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún”.
12. Nígbà tí wọn kéré níye,wọn kéré jọjọ, àti àwọn àjòjì níbẹ̀
13. Wọn ń lọ láti orílẹ̀ èdè sí orílẹ̀ èdè,láti ìjọba kan sí òmìrán.
14. Kò gba ẹnikẹ́ni láàyè láti pọ́n wọn lójú;ó fi ọba bú nítorí tí wọn:
15. “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni àmì òróró mi,má sì ṣe wòlíì mi nibi.”
16. Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náàó sì pa gbogbo ìpèṣè oúnjẹ wọn run;
17. Ó sì rán ọkùnrin kan ṣíwájú wọnJósẹ́fù tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.
18. Wọn fi sẹkẹ́sẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ Rẹ̀a gbé ọrùn Rẹ̀ sínú irin
19. Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọ tẹ́lẹ̀ fi ṣẹtítí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.
20. Ọba ránsẹ́ lọ tú u sílẹ̀àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀
21. Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ Rẹ̀aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,
22. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Rẹ̀, kí ó máaṣe àkóso àwọn ọmọ aládékí ó sì kọ́ àwọn àgbà Rẹ̀ ní ọgbọ́n.
23. Ísírẹ́lì wá sí Éjíbítì;Jákọ́bù sì ṣe àtìpó ní ilé Ámù.
24. Olúwa, sì mú àwọn ọmọ Rẹ̀ bí síió sì mú wọn lágbára jùàwọn ọ̀tá wọn lọ