Sáàmù 105:41-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;gẹ́gẹ́ bí odò tí ń ṣàn níbi gbígbẹ.

42. Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ Rẹ̀àti Ábúráhámù ìránṣẹ́ Rẹ̀.

43. Ó sì fi ayọ̀ mú àwọn ènìyàn Rẹ̀ jádepẹ̀lú ayọ̀ ní ó yan àyànfẹ́ Rẹ̀

44. Ó fún wọn ní ilẹ̀ ìní náà,wọn sì jogún iṣẹ́ àwọn ènìyàn náà,

45. Kí wọn kí ó le máa pa àṣẹ Rẹ̀ mọ́kí wọn kí ó le kíyèsí òfin Rẹ̀.Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Sáàmù 105