30. Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá,èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.
31. Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣnṣin sì dìde,ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn
32. Ó sọ òjò di yìnyín,àti ọ̀wọ́ iná ní ilẹ̀ wọn;
33. Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọnó sì dá igi orílẹ̀ èdè wọn.
34. Ó sọ̀rọ̀, eésú sì dé,àti kòkòrò ní àìníye,
35. Wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn,wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run
36. Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,ààyò gbogbo ipá wọ́n.