28. Ó rán òkùnkùn o sì mú ilẹ̀ ṣúwọn kò sì sọ̀rọ̀ òdì sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀?
29. Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,ó pa ẹja wọn.
30. Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá,èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.
31. Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣnṣin sì dìde,ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn
32. Ó sọ òjò di yìnyín,àti ọ̀wọ́ iná ní ilẹ̀ wọn;
33. Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọnó sì dá igi orílẹ̀ èdè wọn.
34. Ó sọ̀rọ̀, eésú sì dé,àti kòkòrò ní àìníye,