Sáàmù 1:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ó dàbí igi tí a gbìn sí eti odò tí ń ṣàn,tí ń so èso Rẹ̀ jáde ní àkókò Rẹ̀tí ewé Rẹ̀ kì yóò Rẹ̀.Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé,ni yóò máa yọrí sí rere.

4. Kò rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkàtí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.

5. Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

6. Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

Sáàmù 1