15. Ó sì tún wí fún-un pé, “Mú aṣọ ìborùn rẹ tí o dà bora, kí o tẹ̀ ẹ sílẹ̀.” Rúùtù sì ṣe bẹ́ẹ̀, Bóásì sì wọn òṣùwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà sí i, ó sì gbé e rù ú. Nígbà náà ni ó padà sí ìgboro.
16. Nígbà tí Rúùtù dé ilé, Náómì, ìyá ọkọ sì bí léèrè pé, “Báwo ni ó ti rí, ọmọbìnrin mi?”Nígbà náà ni ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún-un, fún ìyá ọkọ rẹ̀.
17. Ó fi kún-un wí pé, “Ó sọ fún mi wí pé, ‘Má ṣe padà sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ ní ọwọ́ òfo, nítorí náà ó fún mi ní ìwọ̀n ọkà bálì mẹ́fà.’ ”
18. Náómì sì wí fún-un pé, “Dúró, ọmọbìnrin mi títí tí ìwọ yóò fi mọ bí ohun gbogbo yóò ti rí. Nítorí pé ọkùnrin náà kò ní sinmi títí tí ọ̀rọ̀ náà yóò fi yanjú lónìí.”