Róòmù 12:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Bí ó le ṣe, bí ó ti wà ní ipa ti yín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.

19. Olùfẹ́, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, “Èmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.”

20. Ṣùgbọ́n bí ebi bá ń pa ọ̀ta rẹ:“Fún un ní oúnjẹ; bí oùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́,fún un ní omi mu;ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí.”

21. Má ṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú.

Róòmù 12