14. Ìdí tí mo fi ń ṣe èyí ni láti mú kí wọn jowú nǹkan tí ẹ̀yin aláìkọlà ní, bóyá ní ọ̀nà yìí Ọlọ́run lè lò mí láti gba díẹ̀ là nínú wọn.
15. Ohun ìyanu ni yóò jẹ́ nígbà tí àwọn Júù yóò di Kírísítẹ́nì. Nígbà tí Ọlọ́run yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ṣe ni ó yípadà sí àwọn ìyókù ní ayé (àwọn aláìkọlà) láti fún wọn ní ìgbàlà. Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú nísinsinyí ìyanu náà ń peléke sí i ni nígbà tí àwọn Júù bá wá sọ́dọ̀ Kírísítì. Bí ẹni pé a sọ àwọn òkú di alààyè ni yóò jẹ́.
16. Níwọ̀n ìgbà tí Ábúráhámù àti àwọn wòlíì jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pẹ̀lú. Ìdí ni pé, bí gbòǹgbò igi bá jẹ́ mímọ́, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú.