Òwe 8:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?

2. Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nàní ìkòríta, ní ó dúró;

3. Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:

4. Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn,

5. Ẹ̀yin aláìmọ́kan, ẹ kọ́gbọ́n;ẹ̀yin aláìgbọ́n, ẹ gba òye.

6. Tẹ́tí, nítorí mo ní àwọn ohun iyebíye láti sọ;Mo ya ẹnu mi láti sọ àwọn ohun tí ó tọ̀nà,

Òwe 8