Òwe 4:5-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Gba ọgbọ́n, gba òye,Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹṣẹ̀ kúrò nínú rẹ̀

6. Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́,fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojú tó ọ.

7. Ọgbọ́n ni ó ga jù; Nítorí náà gba ọgbọ́n.Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye

8. Gbé e ga, yóò sì gbé ọ gadìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.

9. Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹyóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”

10. Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ,Ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.

11. Mo tọ́ ọ sọ́nà ní ọ̀nà ti ọgbọ́nmo sì mú ọ lọ ní ọ̀nà ti tààrà.

12. Nígbà tí o rìn, ìgbẹ́sẹ̀ rẹ kò ní ní ìdíwọ́nígbà tí o bá sáré, iwọ kì yóò kọsẹ̀.

13. Di ẹ̀kọ́ mú, má ṣe jẹ́ kí ó lọ;tọ́jú u rẹ̀ dáradára Nítorí òun ni ìyè rẹ.

14. Má ṣe gbé ẹṣẹ̀ rẹ sí ojú ọnà àwọn ènìyàn búburútàbí kí o rìn ní ọ̀nà àwọn ẹni ibi.

15. Yẹra fún un, má ṣe rìn níbẹ̀;yàgò fún un kí o sì bá ọ̀nà tìrẹ lọ

Òwe 4