Òwe 4:3-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ní ilé baba à mí,mo jẹ́ èwe, tí mo sì jẹ́ ọ̀kanṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi

4. Ó kọ́ mi ó sì wí pé“Jẹ́ kí àyà rẹ kí ó gba ọ̀rọ̀ mi dúró,pa òfin mí mọ́, kí ìwọ kí ó sì yè.

5. Gba ọgbọ́n, gba òye,Má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ mi tàbí kí o yẹṣẹ̀ kúrò nínú rẹ̀

6. Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóò sì dáàbò bò ọ́,fẹ́ràn rẹ̀, yóò sì bojú tó ọ.

7. Ọgbọ́n ni ó ga jù; Nítorí náà gba ọgbọ́n.Bí ó tilẹ̀ ná gbogbo ohun tí o ní, gba òye

8. Gbé e ga, yóò sì gbé ọ gadìrọ̀ mọ́ ọn, yóò sì bu iyì fún ọ.

9. Yóò fi òdòdó ọ̀ṣọ́ ẹwà sí orí rẹyóò sì fi adé ẹlẹ́wà fún ọ.”

10. Tẹ́tí, ọmọ mi, gba ohun tí mo sọ,Ọjọ́ ayé è rẹ yóò sì gùn.

Òwe 4