Òwe 3:14-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.

15. Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;kò sí ohunkohun tí a lè fi wé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.

16. Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;ní ọwọ́ òsì rẹ̀ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.

17. Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ìtura,òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ ti àlàáfíà.

18. Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbàá;àwọn tí ó bá sì dìí mú yóò rí ìbùkún gbà.

19. Nípa ọgbọ́n, Olúwa fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀; nípa òye, ó fi àwọn ọ̀run sí ipòo wọn;

20. Nípa ìmọ̀ rẹ̀ ó pín ibú omi ní ìyà,àwọ̀sánmọ̀ sì ń sẹ ìrì.

Òwe 3