Òwe 28:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. ọba tí ó ni àwọn talákà láradàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ẹ̀gbìn lọ.

4. Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburúṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú.

5. Òye ìdájọ́ òdodo kò yé àwọn ẹni ibiṣùgbọ́n ó yé àwọn tí ń wá Olúwa dáradára.

6. Ó sàn láti jẹ́ talákà tí ìrìn rẹ̀ jẹ́ aláìlábùkùju ọlọ́rọ̀ tí ọ̀nà rẹ̀ rí pálapàla.

7. Ẹni tí ó pa òfin mọ́ jẹ́ olóye ọmọṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹgúdújẹrá kẹ́gbẹ́ dójú ti baba rẹ̀.

Òwe 28