Òwe 22:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ọ̀lẹ wí pé, “Kìnnìún ń bẹ lóde!Ó pa mí ní ìgboro!”

14. Ẹnu àwọn Àṣẹ́wó obìnrín, ihò jínjìn ni;ẹni tí a ń bínú sí láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ni yóò ṣubú sínú rẹ̀.

15. Àyà ọmọdé ni ìwà-wèrè dì sí;ṣùgbọ́n pàṣán ìtọ́ni ni yóò lé e jìnnà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

16. Ẹni tó ń ni talákà lára láti ní ọrọ̀,tí ó sì ń ta ọlọ́rọ̀ lọ́rẹ,yóò di aláìní bí ó ti wù kó rí.Gbọ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn.

17. Dẹtí rẹ sílẹ̀,kí o gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n,kí o sì fi àyà rẹ sí ẹ̀kọ́ mi.

18. Nítorí ohun dídùn ni bí ìwọ bá pa wọ́n mọ́ ní inú rẹ;nígbà tí a sì pèṣè wọn tán ní ètè rẹ.

19. Kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ lè wà níti Olúwa,èmi fi hàn ọ́ lónìí, àní fún ọ.

20. Èmi kò ha ti kọ̀wé ohun dáradárasí ọ níti ìmọ̀ràn àti níti ẹ̀kọ́,

21. Kí ó lè mú ọ mọ dídájú ọ̀rọ̀ òtítọ́;kí ìwọ le máa fi ìdáhùn òtítọ́ fún àwọn tí ó rán ọ?

22. Má ṣe ja talákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ talákà:bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè:

Òwe 22