3. Bí igi ápù láàrin àwọn igi inú igbó,ni olùfẹ́ mí láàrin àwọn ọ̀dọ́mọkùnrinMo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀,Èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu.
4. Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àṣè,Ìfẹ́ sì ni ọ̀pàgun rẹ̀ lórí mi.
5. Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró.Fi èṣo ápù tù mi láraNítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.
6. Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí miỌwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra
7. Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù,mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín búKí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókèKí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú
8. Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi!Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀.Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá,Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kékèké