Orin Sólómónì 1:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Orin àwọn orin tí i ṣe orin Sólómónì

2. Fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kò mí ní ẹnu,nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí wáìnì lọ.

3. Òórùn ìkunra rẹ fanimọ́ra.Orúkọ rẹ rí bí ìkunra tí a tú jádeAbájọ tí àwọn wúndíá fi fẹ́ ọ.

4. Fà mí lọ pẹ̀lú rẹ, kí a lọ kíákíáỌba ti mú mi wá sínú yàrá rẹ̀.Àwa yọ̀ inú wa sì dùn sí ọ;a gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí wáìnì lọ.Wọ́n fẹ́ ọ nítòótọ́!

5. Èmi dúdú mo sì ní ẹwà.Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù,Dúdú bí àgọ́ KédárìBí àgọ́ aṣọ kọ́tìnnì ti Sólómónì

Orin Sólómónì 1