Oníwàásù 10:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún ìpara ní òórùn burúkú,bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀.

2. Ọkàn ọlọgbọ́n a máa sí sí ohun tí ó tọ̀nà,ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára.

3. Kó dà bí ó ti ṣe ń rìn láàrin ọ̀nà,òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́na sì máa fi han gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó.

4. Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ,ma ṣe fi àyè rẹ sílẹ̀;ìdákẹ́jẹ́jẹ́ le è tu àṣìṣe ńlá.

5. Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn,irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.

Oníwàásù 10