21. Ańgẹ́lì Olúwa sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà. Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí ańgẹ́lì náà mọ́.
22. Nígbà tí Gídíónì sì ti mọ̀ dájúdájú pé ańgẹ́lì Olúwa ni, ó ké wí pé, “Háà! Olúwa Ọlọ́run alágbára! Mo ti rí ańgẹ́lì Olúwa ní ojú korojú!”
23. Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Àlàáfíà! Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ kì yóò kú.”
24. Báyìí ni Gídíónì mọ pẹpẹ kan fún Olúwa níbẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “Àlàáfíà ni Olúwa.” Ó sì wà ní Ófírà ti Ábíésérì títí di òní.
25. Ní òru ọjọ́ náà Olúwa wí fún un pé, mú akọ màlúù bàbá rẹ kejì láti inú agbo, akọ màlúù ọlọ́dún méje. Wó pẹpẹ Báálì baba rẹ lulẹ̀, kí o sì fọ́ ọ̀pá Áṣírà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
26. Lẹ́yìn èyí kí o wá mọ pẹpẹ èyí tí ó yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ lórí òkè yìí. Kí o lọ́ igi Áṣírà tí o ké lulẹ̀, kí o fi akọ màlúù kejì rú ẹbọ sísun sí Olúwa.