6. Lẹ́yìn tí Jóṣúà ti tú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ká, àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan lọ sí ilẹ̀ tí a fi fún wọn láti lọ gbà á ní ìní wọn.
7. Àwọn ènìyàn náà sin Olúwa ní gbogbo ìgbà ayé Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbààgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí Olúwa ṣe fún Ísírẹ́lì.
8. Jóṣúà ọmọ Núnì ìránṣẹ́ Olúwa kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110).
9. Wọ́n sì sìnkú rẹ̀ sí ààlà ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní Tímínátì-Hérésì ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù ní àríwá òkè Gásà.
10. Ní ìgbẹ̀yìn, gbogbo ìran náà sì kú; àwọn ìran tí ó tẹ̀lé wọn kò sì sin Olúwa nítorí wọn kò mọ Olúwa bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí Olúwa ṣe fún Ísírẹ́lì.
11. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n sì ń sin òrìṣà Bálímù.
12. Wọ́n kọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn sílẹ̀ ẹni tí ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n ń tọ àwọn òrìṣà lẹ́yìn, wọ́n sì ń sin àwọn oríṣìíriṣí òrìṣà àwọn ará ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú Olúwa bínú.