36. Wọ́n kúrò ní Esoni-Gébérì wọ́n sì pàgọ́ ní Kádésì nínú ihà Ṣínì.
37. Wọ́n kúrò ní Kádésì wọ́n sì pàgọ́ ní orí òkè Hórì, lẹ́bá Édómù.
38. Nípa àsẹ Olúwa, Árónì àlùfáà gùn orí òkè Hórì, níbẹ̀ ni ó kú. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kárun, ọdún ogójì, lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ilẹ̀ Éjíbítì jáde wá.
39. Árónì jẹ́ ẹni ọgọ́fà ọdún ó lé mẹ́ta ní ìgbà tí ó kú sí orí òkè Hórì.
40. Àwọn ará Kénánì, ọba Árádì, tí ń gbé ìhà gúṣù ní ilẹ̀ Kénánì gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bọ̀.
41. Wọ́n kúrò ní orí òkè Hórì, wọ́n sì pàgọ́ ní Ṣálímónà.
42. Wọ́n kúrò ní Ṣálímónà wọ́n sì pàgọ́ ní Púnónì.