Nọ́ḿbà 3:41-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Kí o sì gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Léfì fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Èmi ni Olúwa.”

42. Mósè sì ka gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

43. Àpapọ̀ iye àwọn àkọ́bí ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan ó lé, ní àkọsílẹ̀ orúkọ wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé ọ̀rìnlúgba ó dín méje (22,273).

44. Olúwa tún sọ fún Mósè pé,

45. Gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Léfì dípò ohun ọ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Tèmi ni àwọn ọmọ Léfì. Èmi ni Olúwa.

46. Nísinsin yìí, láti lè ra ọ̀rìnlúgba dín méje (273) àkọ́bí àwọn Ísírẹ́lì tó ju iye àwọn ọmọ Léfì lọ,

47. ìwọ yóò gba sẹ́kẹ́lì márùn ún (5) lórí ẹni kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́, èyí tí í ṣe ogún gérà.

Nọ́ḿbà 3