Nọ́ḿbà 29:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “ ‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù keje, kí ẹ ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Ọjọ́ ìfúnpè ni ó jẹ́ fún yín.

2. Gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa, ẹ pèsè ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù, kí ẹ fi ẹbọ sísun.

3. Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kan, àti ìdáméjì nínú mẹ́wàá, òṣùwọ̀n fún àgbò kan,

4. àti ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n fún ọ̀dọ́ àgùntàn kan, àti fún ọ̀dọ́ àgùntàn méje.

Nọ́ḿbà 29