Nọ́ḿbà 27:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọmọbìnrin Ṣélóféhátì ọmọ Héférì, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírì ọmọ Mánásè tó jẹ́ ìdílé Mánásè, ọmọ Jósẹ́fù wá. Orúkọ àwọn ọmọbìnrin náà ni Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tásà.

2. Wọ́n súnmọ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé wọ́n sì dúró níwájú Mósè, àti Élíásérì àlùfáà, àti níwájú àwọn olórí àti ìjọ, wọ́n sì wí pé,

3. “Baba wa kú sí ihà. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kórà tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, Ṣùgbọ́n ó kú nítórí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀.

Nọ́ḿbà 27