11. Mo sì lọ sí Jérúsálẹ́mù, lẹ́yìn ìgbà tí mo dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.
12. Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀. Èmi kò sì sọ fún ẹnikankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jérúsálẹ́mù. Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lúu mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn.
13. Ní òru, mo jáde lọ sí àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jákálì àti sí ẹnu ibodè jààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun.
14. Nígbà náà ni mo lọ sí ẹnu ibodè oríṣun àti sí adágún omi ọba, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tó fún ẹranko mi láti kọjá;
15. Bẹ́ẹ̀ ni mo gòkè àfonífojì ní òru, mo ń wo odi. Ní ìparí, mo padà ṣẹ́yìn, mo sì tún wọlé láti ibodè àfonífojì.