Nehemáyà 11:19-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Àwọn aṣọ́nà:Ákúbù, Tálímónì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n máa ń ṣọ́nà jẹ́ méjìléláàdọ́-sàn-án (172) ọkùnrin.

20. Àwọn tó kù nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, wà ní gbogbo ìlúu Júdà, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìníi tirẹ̀.

21. Àwọn ìránṣẹ́ẹ tẹ́ḿpílì ń gbé lórí òkè òfélì, Ṣíhà àti Gíṣípà sì ni alábojútó wọn.

22. Olórí òṣìṣẹ́ àwọn ọmọ Léfì ní Jérúsálẹ́mù ní Húsì ọmọ Bánì, ọmọ Hásábíà, ọmọ Mátaníyà ọmọ Míkà. Húṣì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìran Áṣáfù tí wọ́n jẹ́ akọrin ojúṣe nínú ìjọsìn ní ilé Ọlọ́run.

23. Àwọn akọrin wà ní abẹ́ àṣẹ ọba, èyí tí ó n díwọ̀n iṣẹ́ ojoojúmọ́ọ wọn.

24. Petaiayọ̀ ọmọ Meṣeṣabélì, ọ̀kan nínú àwọn Ṣérà ọmọ Júdà ní aṣojú ọba nínú ohun gbogbo tí ó jẹ mọ́ ti àwọn ènìyàn náà.

Nehemáyà 11