Nehemáyà 11:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ṣéráyà ọmọ Hílíkáyà, ọmọ Mésúlámù, ọmọ Ṣádókì, ọmọ Méráótì, ọmọ Áhítúbì alábojútó ní ilé Ọlọ́run,

12. àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ní tẹ́ḿpìlì jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́rinlélógún (822) ọkùnrin: Ádáyà ọmọ Jéróhámù, ọmọ Péláyà, ọmọ Ámísì, ọmọ Ṣakaráyà, ọmọ Pásúrì, ọmọ Málíkíjà,

13. àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olórí ìdílé jẹ́ òjìlúgba ó lé méjì (242) ọkùnrin: Ámáṣíṣáì ọmọ Áṣárélì, ọmọ Áṣáì, ọmọ Méṣílémótì, ọmọ Ìmérì,

14. àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alágbára ọkúnrin jẹ́ méjìdínláàdọ́je (128). Olórí òṣìṣẹ́ ẹ wọn ni Sábídíelì ọmọ Hágédólímù.

15. Láti inú àwọn ọmọ Léfì:Ṣémáyà ọmọ Háṣúbù, ọmọ Ásíríkámù, ọmọ Háṣábíyà ọmọ Búnì;

16. Ṣábétaì àti Jóṣábádì, olórí méjì nínú àwọn ọmọ Léfì, àwọn tí ó jẹ́ alábojútó iṣẹ́ tí ó wà ní ẹ̀yìn àgbàlá ilé Ọlọ́run;

17. Mátaníyà ọmọ Míkà, ọmọ Ṣábídì, ọmọ Áṣáfì, adarí tí ó rí ṣáájú ìdúpẹ́ àti àdúrà; Bákíbúkíyà ẹnìkejì láàrin àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀; àti Ábídà ọmọ Ṣámúyà, ọmọ Gálálì, ọmọ Jédútúmù.

18. Àwọn ọmọ Léfì nínú ìlú mímọ́ jẹ́ ọ̀rìnlélúgba ó lé mẹ́rin (284).

19. Àwọn aṣọ́nà:Ákúbù, Tálímónì, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, tí wọ́n máa ń ṣọ́nà jẹ́ méjìléláàdọ́-sàn-án (172) ọkùnrin.

20. Àwọn tó kù nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, wà ní gbogbo ìlúu Júdà, olúkúlùkù lórí ilẹ̀ ìníi tirẹ̀.

21. Àwọn ìránṣẹ́ẹ tẹ́ḿpílì ń gbé lórí òkè òfélì, Ṣíhà àti Gíṣípà sì ni alábojútó wọn.

Nehemáyà 11