14. Nítorí náà ni ìwọ ó ṣe fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀fún Mórésétígátì.Àwọn ilé Ákísíbì yóò jẹ́ ẹlẹ̀tàn sí àwọn ọba Ísírẹ́lì.
15. Èmi yóò sì mú àrólé kan wá sórí rẹ ìwọ olùgbé Máréṣà.Ẹni tí ó jẹ́ ogo Ísírẹ́lìyóò sì wá sí Ádúlámù.
16. Fá irun orí rẹ nínú ọ̀fọ̀nítorí àwọn ọmọ rẹ aláìlágbára,sọ ra rẹ̀ di apárí bí ẹyẹ igún,nítorí wọn yóò kúrò lọ́dọ̀ rẹ lọ sí ìgbèkùn.