Mátíù 3:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ẹni ti ìmúga ìpakà Rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, yóò gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀, yóò kó ọkà rẹ̀ sínú àká, ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.”

13. Nígbà náà ni Jésù ti Gálílì wá sí odò Jọ́dánì kí Jòhánù báà lè ṣe ìtẹ̀bọmi fún un.

14. Ṣùgbọ́n Jòhánù kò fẹ́ ṣe ìtẹ̀bọmi fún un, ó wí pé, “Ìwọ ni ì bá ṣe ìbamitíìsì fún mi, ṣé ìwọ tọ̀ mí wá fún ìbamitíìsì?”

15. Jésù sì dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà, ní torí bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ fún wa láti mú gbogbo òdodo ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Jòhánù gbà, ó sì ṣe ìbamitíìsì fún un.

Mátíù 3