Mátíù 18:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í léèrè pé, “Ta ni ẹni ti ó tóbi jùlọ ní ìjọba ọ̀run?”

2. Jésù sì pe ọmọ kékeré kan sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀. Ó sì mú un dúró láàrin wọn.

Mátíù 18