Mátíù 16:8-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èé ṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́?

9. Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsìn yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹẹ́dọ́gbọ́n (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìsù búrẹ́dì márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kó jọ bí àjẹkù?

10. Ẹ kò sì tún rántí ìsù méje tí mo fi bọ́ ẹgbààjì (4,000) ènìyàn àti iye àjẹkù tí ẹ kó jọ?

11. È é ha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti búrẹ́dì? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ti Sadusí.”

12. Nígbà náà ni ó ṣẹ̀sẹ̀ wá yé wọn pé, kì í ṣe nípa ti ìwúkàrà ní ó sọ wí pé kí wọ́n kíyè sára, bí kò se tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti Sadusí.

13. Nígbà tí Jésù sì dé Kesaríà-Fílípì, ó bi àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi Ọmọ ènìyàn pè?”

14. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ni Jòhánù onítẹ̀bọ́mì ni, àwọn mìíràn wí pé, Èlíjà ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremáyà ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”

Mátíù 16