Mátíù 1:9-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Húsáyà ni baba Jótámù;Jótámù ni baba Áhásì;Áhásì ni baba Heṣekáyà;

10. Heṣekáyà ni baba Mánásè;Mánásè ni baba Ámónì;Ámónì ni baba Jósáyà;

11. Jósáyà sì ni baba Jékónáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Bábílónì.

12. Lẹ́yìn ìkólọ sí Bábílónì:Jékónáyà ni baba Selítílì;Selítílì ni baba Sérúbábélì;

13. Sèrérúbábélì ni baba Ábíúdì;Ábíúdì ni baba Élíákímù;Élíákímù ni baba Ásórì;

14. Ásórì ni baba Sádókù;Sádókù ni baba Ákímù;Ákímù ni baba Élíúdì;

15. Élíúdì ni baba Élíásárì;Élíásárì ni baba Mátítánì;Mátítánì ni baba Jákọ́bù;

16. Jákọ́bù ni baba Jósẹ́fù, ẹni tí ń ṣe ọkọ Màríà, ìyá Jésù, ẹni tí í ṣe Kírísítì.

17. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́ ìran mẹ́rìnlá láti orí Ábúráhámù dé orí Dáfídì, ìran mẹ́rìnlà á láti orí Dáfídì títí dé ìkólọ sí Bábílónì, àti ìran mẹ́rìnlà láti ìkólọ títí dé orí Kírísítì.

18. Bí a ṣe bí Jésù nì yìí: Ní àkókò ti àdéhùn ìgbéyàwó ti parí láàrin Màríà ìyá rẹ̀ àti Jósẹ́fù, ṣùgbọ́n kí wọn tó pàdé, a rí i ó lóyún láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́.

19. Nítorí Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀ tí í ṣe olóòótọ́ ènìyàn kò fẹ́ dójú tì í ní gbangba, ó ní èrò láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.

Mátíù 1