Mátíù 1:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìran Jésù Kírísítì, ẹni tí í ṣe ọmọ Dáfídì, ọmọ Ábúráhámù:

2. Ábúráhámù ni baba Ísáákì;Ísáákì ni baba Jákọ́bù;Jákọ́bù ni baba Júdà àti àwọn arákùnrin rẹ̀,

3. Júdà ni baba Pérésì àti Ṣérà,Támárì sì ni ìyá rẹ̀,Pérésì ni baba Ésírónù:Ésírónù ni baba Rámù;

4. Rámù ni baba Ámínádábù;Ámínádábù ni baba Náhísónì;Náhísónì ni baba Sálímónì;

5. Sálímónì ni baba Bóásì, Ráhábù sí ni ìyá rẹ̀;Bóásì ni baba Óbédì, Rúùtù sí ni ìyá rẹ̀;Óbédì sì ni baba Jésè;

6. Jésè ni baba Dáfídì ọba.Dáfídì ni baba Sólómónì, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Húráyà tẹ́lẹ̀ rí.

7. Sólómónì ni baba Réhóbóámù,Réhóbóámù ni baba Ábíjà,Ábíjà ni baba Ásà,

Mátíù 1