Máàkù 7:34-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Nígbà náà ni Jésù wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, “Éfátà,” èyí ni, “Ìwọ ṣí.”

35. Bí Jésù ti pàṣẹ yìí tan, ọkùnrin náà sì gbọ́ràn dáadáa. Ó sì sọ̀rọ̀ ketekete.

36. Jésù pàṣẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà níbẹ̀ pé kí wọn má ṣe tan ìròyìn náà ká. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń pa wọ́n lẹ́nu mọ́ tó, náà ni wọ́n ń tan ìròyìn náà káàkiri tó.

37. Àwọn ènìyàn sì kún fún ìyanu, wọ́n wí pé, “Ó se ohun gbogbo dáradára, Ó mú kí adití gbọ́ràn, odi sì sọ̀rọ̀.”

Máàkù 7