Máàkù 13:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìyìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀ èdè kí òpin tó dé.

11. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá mú yín, tí ẹ sì dúró níwájú adájọ́, ẹ má ṣe dààmú nípa ohun tí ẹ ó wí fún ààbò. Ẹ ṣáà sọ ohun tí Ọlọ́run bá fi sí yín lọ́kàn. Ẹ̀yin kọ́ ní yóò sọ̀rọ̀, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́.

12. “Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣekú pa òbí wọn.

Máàkù 13