Máàkù 10:19-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ìwọ mọ àwọn òfin bí i: Má ṣe pànìyàn, má ṣe panṣágà, má ṣe jalè, má ṣe purọ́, má ṣe rẹ́ ọmọnìkejì jẹ, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.”

20. Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń ṣe láti ìgbà èwe mi wá.”

21. Jésù wò ó tìfẹ́tìfẹ́. Ó wí fún un pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan ló kù fún ọ láti ṣe, lọ nísinsìn yìí, ta gbogbo nǹkan tí o ní, kí o sì pín owó náà fún àwọn aláìníìwọ yóò sì ni ìsura ní ọ̀run, sì wá, gbe àgbélébú, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

22. Nígbà tí ọkùnrin yìí gbọ́ èyí, ojú rẹ̀ korò, ó sì lọ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí pé ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

23. Jésù wò ó bí ọkùnrin náà ti ń lọ. Ó yípadà, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àní, ohun ìṣòro ni fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!”

24. Ọ̀rọ̀ yìí ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu. Jésù tún sọ fún wọn pé, “Ẹ ẹ̀yin ènìyàn yóò tí ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run.

25. Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ kan láti wọ ìjọba ọ̀run.”

26. Ẹnu túbọ̀ ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sí i. Wọ́n béèrè wí pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni nínú ayé ti ó lè ní ìgbàlà?”

27. Jésù wò wọ́n? ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ní èyí kò se é ṣe fún ṣùgbọ́n kì í ṣe fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ni síṣe fún Ọlọ́run.”

28. Nígbà náà ni Pétérù kọjú sí Jésù, ó wí pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”

Máàkù 10