1. Ìbẹ̀rẹ̀ ìyìnrere nípa Jésù Kírísítì, Ọmọ Ọlọ́run.
2. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Àìṣáyà pé:“Èmi yóò ran oníṣẹ́ mí ṣíwájú rẹ,Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.”
3. “Ohùn ẹnìkan tí ń kígbe ní ihà,‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,ẹ se ojú-ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ”
4. Jòhánù dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní ihà, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.
5. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Jùdíà, àti gbogbo ènìyàn Jerúsálémù jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọmi ni odò Jọ́dánì, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
6. Jòhánù sì wọ ẹ̀wù tí a fi irun ràkúnmí hun. Ó sì lo ìgbànú awọ. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀.
7. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹṣẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú.
8. Èmi ń fi omi se ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ se ìtẹ̀bọmi yín.”
9. Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jésù ti Násárẹ́tì ti Gálílì jáde wá, a sì ti ọwọ́ Jòhánù tẹ̀ Ẹ bọmi ní odò Jọ́dánì.
10. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jésù ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó sí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọkalẹ̀ lé E lórí.
11. Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ìwọ ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
12. Lẹ́sẹ̀kan-náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jésù sí ihà,
13. Ó sì wà níbẹ̀ fún ogójì ọjọ́. A sì fi Í lé Èṣù lọ́wọ́ láti dán an wò. Àwọn ańgẹ́lì sì wá ṣe ìtọ́jú Rẹ̀.
14. Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Hẹ́rọ́dù ti fi Jòhánù sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jésù lọ sí Gálílì, ó ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba Ọlọ́run.
15. Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dèdè. Ẹ yípadà kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.”
16. Ní ọjọ́ kan, bí Jésù ti ń rìn létí òkun Gálílì, Ó rí Ṣímónì àti Ańdérù arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé Apẹja ni wọ́n.
17. Jésù sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”
18. Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.