Lúùkù 9:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí ẹ̀sù gbogbo, àti láti wo àrùn sàn.

2. Ó sì rán wọn lọ wàásù ìjọba Ọlọ́run, àti láti mú àwọn ọlọkùnrùn láradá.

3. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkan lọ fún àjò yín, ọ̀pá, tàbí àpò tàbí àkàrà, tàbí owó: bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má sì ṣe ní ẹ̀wù méjì.

4. Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin gbé, láti ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin sì ti jáde.

Lúùkù 9