40. Jésù sì dáhùn, ó wí fún un pé, “Símónì, Mo ní ohun kan sọ fún ọ.”Ó sì dáhùn pé, “Olùkọ́ máa wí.”
41. “Ayánilówó kan wà tí ó ní ajigbésè méjì: ọ̀kan jẹ ẹ́ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta owó idẹ, èkejì sì jẹ ẹ́ ní àádọ́ta.
42. Nígbà tí wọn kò sì ní ohun tí wọn ó san, ó dáríji àwọn méjèèjì. Wí nínú àwọn méjèèjì, tani yóò fẹ́ ẹ jù?”
43. Símónì dáhùn wí pé, “Mo ṣebí ẹni tí ó dáríjìn jù ni.”Ó wí fún un pé, “O wí i re.”
44. Ó sì yípadà sí obìnrin náà, ó wí fún Símónì pé, “Wo obìnrin yìí? Èmi wọ ilé rẹ, ìwọ kò fi omi wẹ ẹṣẹ̀ fún mi: ṣùgbọ́n òun, omije rẹ̀ ni ó fi ń rọ̀jò sí mi lẹ́sẹ̀ irun orí ni ó fi n nù wọ́n nù.
45. Ìwọ kò fi ìfẹnukonu fún mi: ṣùgbọ́n òun, nígbà tí mo ti wọ ilé, kò dẹ́kun ẹnu fífi kò mí lẹ́ṣẹ̀.